ỌBA MÉJÌ GBA Ọ̀PÁ ÀṢẸ LỌ́JỌ́ KAN ṢOṢO NI KWARA, L'AWỌN ARÁÀLÚ BA LÀWỌN BỌ SÁYÉ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, November 24, 2020

ỌBA MÉJÌ GBA Ọ̀PÁ ÀṢẸ LỌ́JỌ́ KAN ṢOṢO NI KWARA, L'AWỌN ARÁÀLÚ BA LÀWỌN BỌ SÁYÉ


Ọjọ́ Aje-Mọndee àná ni Gómìnà ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq gbé ọ̀pá àṣẹ àti ìwé àṣẹ lè Ọba Haruna Ọlawale Suleiman gẹ́gẹ́ bí Olupako tilu Share àti Ọba Ajibọla Ademọla Julius tòun jẹ Oluṣin tilu Ijara-Iṣin. 

Titi di àsìkò tá a parí ìròyìn yìí làwọn aráàlú ṣí ń yọ, tí wọn ń dunnu lórí bí wọn ṣe fi ọba tuntun dá wọn lọ́lá, tí wọn sì ń sọ pé oriire ńlá ló wọlé tọ wọn. 


Níbi eto ayẹyẹ náà ni Gómìnà AbdulRazaq tí gba àwọn ọba náà lamọran pé kí wọn gbìyànjú láti máa wà àlàáfíà, ìṣọ̀kan àti irẹpọ láàárín ìlú wọn. 

Gómìnà AbdulRazaq jẹ́ kó di mimọ pé ipa àti akitiyan àwọn ọba alaye nínú ètò ìdàgbàsókè ìlú kò ṣeé fọwọ́ rọ sẹyin, àti pé àwọn gan án ní aṣiwaju tó ń gbé àlàáfíà àti ìṣọ̀kan lárugẹ. 
 
Ó tẹsiwaju pé ìṣàkóso òun gẹ́gẹ́ bí ìlérí àti ìpinnu òun yóò máa ṣagbatẹru àwùjọ àwọn ọba tòun yóò sì máa ṣe iranlọwọ tó bá yẹ fún wọn.




No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI