Lasiko ti a ṣakojọpọ iroyin yii tan, inu ibẹrubojo ati aibalẹ-ọkan l'awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria jakejado agbaye wa lori asọtẹlẹ ibẹru ti ogbontarigi iranṣẹ Ọlọrun nni, Wolii Elijah Ayọdele sọ pe yoo ṣẹlẹ laipẹ.
Ki i ṣe akọkọ ree ti Wolii Ayọdele yoo maa sọ asọtẹlẹ nipa orilẹ-ede Naijiria ati agbaye, t'awọn asọtẹlẹ naa si ti wa si imuṣẹ, eyi gan an lo n kọ ibẹru s'ọkan awọn araalu.
Lasiko to n báwọn oniroyin sọrọ, Primate Elijah Ayọdele sọ pe pupọ awọn banki ni yoo fori ṣanpọn l'ọdun 2021 to n bọ yii, ati pe idarudapọ yoo waye lorilẹ-ede Naijiria, ti ko si ni i ye ẹnikẹni.
Primate Ayọdele ni asiko naa n bọ t'awọn eeyan ko ni le lọ si ibiṣẹ wọn mọ nitori idarudapọ ati wahala yoo ti waye, ati pe ko si ọmọ orilẹ-ede Naijiria kankan ti yoo gbadun iṣẹjọ to wa nita lasiko yii.
O sọ siwaju pe ko ba fẹẹ koju ifasẹyin nipa eto ọrọ aje onikaluku, afi ki wọn gbadura ati aawẹ laaarin ọjọ kinni si ọjọ kẹrinla oṣu kinni ọdun 2021.
No comments:
Post a Comment