Gómìnà ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq tí sọ pé ìṣàkóso òun yóò ṣe iranlọwọ fáwọn ileeṣẹ àti àwọn olokoowo táwọn tọọgi bá dúkìá wọn jẹ, tí wọn sì tún kó wọn lẹ́rù lọ lásìkò iwọde ifẹhonuhàn láti fi òpin sí àwọn ọlọpaa SARS káàkiri orílẹ̀-èdè Nàìjíríà
Bí ẹ ṣe ń ka ìròyìn yìí, ìjọba tí gbé igbimọ ẹlẹni mọ́kànlá dìde láti ṣe ìwádìí àwọn tí ileeṣẹ wọn àti okoowo wọn fara kááṣá lásìkò rògbòdìyàn náà n'ilu Ilọrin.
Àwọn igbimọ yìí là gbọ pé wọn yóò ṣe ìwádìí láti mọ iye àwọn nǹkan táwọn tọọgi bajẹ fún ìjọba láti pèsè owó iranwọ fún wọn, kí ọjà wọn lé túbọ̀ padà bọ̀ sípò tó wà tẹ́lẹ̀.
Igbakeji Gómìnà, Kayọde Alabi ni alaga igbimọ ẹlẹni mọ́kànlá náà, tí wọn sì tún yàn àwọn èèyàn tó ṣeé fi ọkàn tán láwùjọ láti lè jẹ ki iṣẹ náà tètè ya.
No comments:
Post a Comment