Akowe ijọba ipinlẹ Niger, Ahmed Matane ti sọ pe irọ to jinna si otitọ patapata ni pe awọn kọmiṣanna mẹta kan ti ko ajakalẹ arun koronafairọọsi.
Matane, ẹni to tun jẹ alaga igbimọ to n ri sọrọ arun naa lo sọrọ naa lonii ni nu atẹjade to fi sita f'awọn oniroyin, nibi to ti sọ pe awọn to n gbe iroyin naa kaakiri ko mọ nnkan ti wọn n ṣe.
O ni ohun to ṣeni laanu ni pe awọn ileeṣẹ iwe iroyin to gbajumọ daadaa lorilẹ-ede yii naa tun pẹlu awọn to n gbe iroyin naa kaakiri, to si ni wọn ko ri okodoro ko to di pe wọn gbe e jade sita.
Matane wa a gba awọn eeyan lamọran wi pe ki wọn ma ṣe gbagbọ ninu iroyin naa, nitori pe ko si ohun to jọ bẹẹ rara, ati pe ayederu ni iroyin naa.
No comments:
Post a Comment