Ki i ṣe ahesọ mọ pe oni ni ayẹyẹ ọgọta ọdun gómìnà ana n'ìpińlẹ̀ Ekiti Ọgbẹni Peter Ayọdele Fayoṣe, tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí "Oṣokomọlẹ Peter the Rock".
B'awọn eeyan kaakiri agbaye, paapaa awọn ololufẹ rẹ ṣe n ki i ku oriire naa ni ileeṣẹ AWIKONKO n gbadura fun un pe Ọlọrun yoo jẹ ki awọn ileri rere rẹ wa si imuṣẹ pẹlu ogo Ọlọrun.
Nibi eto ayẹyẹ ọgọta ọdun naa, eyi to n lọ lọwọ ni Peter Ayọdele Fasyoṣe sọ idi pataki to fi maa n tako Aarẹ tẹlẹri lọrilẹ-ede yii, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ lọpọ igba, to si ni ọrọ wọn maa n tako ara wọn ni, ati pe ko si ija kankan laarin wọn.
Bakan naa lo tọrọ aforiji lọwọ Ọbasanjọ, to si ni ọmọde ko le mọ ẹkọ ọ jẹ ko ma ra a lọwọ.
Ninu ọrọ Fayoṣe lo ti sọ pe "
Kò sí ìdí tí mó fi fẹ̀ẹ tọrọ àforijì lọ́wọ́ Baba Ọbasanjọ, nítori kò sí ǹkankan tó wà láàrín àwọn gẹ́gẹ́ bi awọn kan ṣe n ro. Ọpọ igba l'awọn ọrọ awa mejeeji maa n tako ara wọ, eyi to jẹ k'awọn kan maa lero wi pe ija wa laarin wa, ko ri bẹẹ rara."
Siwaju si i, Fayoṣe ni ní àsìkò yìí gan an ló yẹ láti jòkóo láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlórun àti láti súnmọ́ síi.
Nínú ìfọ̀rọ̀wánílẹ̀wò ní Fayoṣe ti ṣàlàyé pé, ní ọ̀pọ̀ ìgbà, ìyáwó òun ní ìrùmi tó ń lùlù lábẹ́ odó tí t'oun fi n jó lóke omi.
"Sùgbọ́n lásìkò àyẹyẹ ọgọ́ta ọdún yìí, ó ṣe pàtàkì láti súnmọ Ọlọ́run, kí ènìyàn sì máa ṣètò àti ló ìgbẹ̀yìn àyé ẹ lo ku.
"Bí Ọlọrun ṣe fún mi ni ẹmi gígùn, ó ṣe pàtàkì láti fi ayé wa fún, láti wo àwọn ọ̀nà ti kò dara, eyi tí à ń rìn àti láti máa wá ọ̀nà láti wà ni ọnà àláfíà pẹ̀lú Ọlọ̀run.
Ó ní tíì kìí bá ṣe pé ìyàwó tí òun fẹ́ ni, ó ṣée ṣe kí òun ti dí ẹni àgbégbìn nítorí ọ̀tá yóò tí ké òun kúrò.
"Ìyàwó mi ni alárínà láàrín èmi àti Ọlọ́run. Láàrín òru yóò ji, yóò di ẹsẹ̀ mi mú, yóò si máa gba àdúrà"
"Mó fí ọjọ́ ìbí yìí ji ìyàwò mi àti Ọlọ́run."
Bakan naa lo tun fi idaniloju naa sita wi pe oun ṣi nígbagbọ lati di Aarẹ orilẹ-ede Naijiria lọjọ kan, to si ni ko sẹni to le yi ipinnu Ọlọrun pada.
O tun sọrọ nipa awuyewuye to wà láàrín oun àti gómìnà ìpińlẹ̀ Ọyọ, Ṣeyi Makinde. Fayose ni òun kò ni yée sọ òótọ́ ọ̀rọ̀ nígbà tí ó bá yẹ.
"Kò sí ǹkankan ti èmi àti Makinde ń fa, ṣùgbọ́n ó ṣe pàtàkì kí olúkùlùkù kọjú mọ́ agbègbè rẹ̀ nìkan gẹ́gẹ́ bi ofin ẹgbẹ́ Makinde ni olórí adari PDP ni ẹkùn, sùgbọ́n kìí ṣe gómìnà àwọn ìpínlẹ̀ tó wa ní abẹ́ rẹ̀."
No comments:
Post a Comment