Itan nla ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tun fẹẹ fi balẹ yii pẹlu bo ṣe ti bẹrẹ kikọ ọsibitu nla to tobi julọ, nibi ti wọn yoo ti maa ṣe awọn iṣẹ abẹ loriṣiriṣi nilẹ Hausa, eyi ti wọn pe ni Neurology and Neurosurgery Centre in North Central pẹlu ẹka ti wọn pe ni Intensive Care Unit (ICU), ati wọọdu.
Inu ọgba ọsibitu ijọba t'ipinlẹ naa, iyẹn jẹnẹra la gbọ pe wọn n kọ ọsibitu yii si lojuna lati le jẹ k'awọn araalu jẹ anfaani eto ilera ti ijọba awaarawa.
Laipẹ yii ni Gomina AbdulRazaq ṣe abẹwo si ibi t'awọn agbaṣẹṣe naa ti n ṣiṣẹ lọwọ, ti wọn si ṣalaye fun un pe ko ni pẹ ti wọn yoo fi pari akanṣe iṣẹ naa fun igbadun araalu.
No comments:
Post a Comment