IPINLẸ KWARA ṢI SILẸ FUN OKOOWO ṢIṢE - IJỌBA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, November 19, 2020

IPINLẸ KWARA ṢI SILẸ FUN OKOOWO ṢIṢE - IJỌBA


Gomina AgdulRahman AbdulRazaq t'ipinlẹ Kwara ti sọ pe ipinlẹ naa ti ṣi silẹ f'awọn olokoowo keekeeke ati nla lati wa a ṣe ọrọ aje nibẹ, tori pe gbogbo ohun amayedẹrun n'ijọba ti pese.
 
Ana ti i ṣe Ọjọru-Wẹsidee ni Gomina AbdulRazaq bu ọwọ lu ofin ileeṣẹ to n ṣe abelarugẹ awọn ileeṣẹ ati okoowo n'ipinlẹ naa, iyẹn Kwara Investment Promotion Agency {KWIPA}. 
 
"Ọna lati yọ wahala ati idaamu kuro l'ọrun ijọba lo mu ka gbe igbesẹ yii, nitori pe ileeṣẹ yii ni yoo jẹ anfaani f'awọn onimọ nipa okoowo lati da iṣẹ ati ileeṣẹ silẹ. Ati pe ipinlẹ naa ko tun le maa duro de owo lati ọdọ ijọba apapọ loṣooṣu mọ ki wọn to o dawọ le ohunkohun." gẹgẹ bi Gomina AbdulRazaq ṣe sọ.
 
Lara awọn to wa nibẹ ni: abẹnugọn ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa, Ọnọrebu Yakubu Danladi Salihu; Ọnọrebu Ọlawọyin Magaji; agbọpa ile igbimọ aṣofin, Halimah Jummai Kperogi; awọn oloye ẹgbẹ oṣelu APC bi i Yahya Seriki ati Musibau Ẹsinrogunjo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI