Ṣẹnkẹn bayii ni inu gbogbo awọn ọmọ bibi ipinlẹ Kwara n dun lori ọkan lara ọmọ wọn to jawe olubori ninu idibo to waye nilẹ Amẹrika l'ọjọ Iṣẹgun-Tuside anaa.
Gomina ipinlẹ naa, AbdulRahman AbdulRazaq ti fi idunnu rẹ han wi pe ọkan lara awọn ọmọ bibi ipinlẹ oun to n gbe orukọ ipinlẹ Kwara larugẹ kaakiri agbaye.
Oye Owolẹwa, wa lara awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria to gbe apoti nilẹ Amẹrika lọdun yii, toun si lọọ ṣoju gẹgẹ bi aṣoju-ṣofin fun Washington DC.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, Owolẹwa ni iwe igbelu, toun naa si tun ti di ọkan lara awọn ọmọ ilẹ Amẹrika to lẹtọọ lati du ipo yoowu.
Ilu Omu-Aran nípinlẹ Kwara ni Owolẹwa ti wa.
N'igba to n fi idunnu rẹ han, Gomina AbdulRazaq ni bi ọkunrin naa ṣe jawe olubori ti fi han daju pe awọn eeyan nifẹẹ rẹ gidi, ati pe lori otitọ ati iwa rere rẹ lo mu ko jawe olubori.
Siwaju si i lo tun ki gbogbo awọn ọmó ẹgbẹ ipinlẹ Kwara ti wọn n gbe ni North Amẹrika, paapaa Alaaji Lateef Amọlẹgbẹ ku oriire to wọle tọ wọn, to si n gbawọn ọmọ ipinlẹ naa lamọnran pe ki wọn gbiyanju lati maa jẹ apẹẹrẹ rere to ṣee tọka si.
No comments:
Post a Comment