IBẸRUBOJO TUN B'AWỌN ARA ÈKÓ LÓRÍ WÀHÁLÀ AWỌN ỌLỌKADA ÀTÀWỌN AGBOFINRO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, November 18, 2020

IBẸRUBOJO TUN B'AWỌN ARA ÈKÓ LÓRÍ WÀHÁLÀ AWỌN ỌLỌKADA ÀTÀWỌN AGBOFINRO


Pẹ̀lú bí nnkan ṣe ń lọ yìí, afaimọ ni kí ìṣẹ̀lẹ̀ náà má tún kọjá ojú tàwọn èèyàn fi ń wo ó, kò má sì lọ dàbí ìṣẹ̀lẹ̀ tí #ENDSARS tó dá nnkan ru mọ àwọn èèyàn tó fi mọ ìjọba lójú. 

Lati ọjọ́ Iṣẹgun-Tusidee àná ni wàhálà àwọn ọlọkada àtàwọn agbófinró tí bẹ̀rẹ̀ n'ilu Èkó, nígbà tí wọn làwọn agbófinró kò fi àwọn ọlọkada lọ́kàn balẹ̀. 

AWIKONKO gbọ pé àwọn agbófinró ipinlẹ Èkó, ìyẹn Lagos State Task Force ni wọn ń dunkooko mọ àwọn ọlọkada lórí àwọn òpópónà tí wọn ń gbà. 

Ní nǹkan bí oṣù mélòó kan sẹ́yìn ni ìjọba gbé òfin tuntun jáde síta wí pé àwọn ọlọkada kò gbọ́dọ̀ rìn tàbí ṣiṣẹ́ làwọn òpópónà ńláńlá, ìyẹn àwọn òpópónà marosẹ láti lè dẹkùn ìjàmbá àti sunkẹrẹ-fakẹrẹ. 

Ṣe ni wàhálà ńlá déédéé ṣẹyọ lọ́jọ́ Tusidee lagbegbe Second Rainbow to wa lopopona Apapa-Oṣodi n'igba ti wọn l'awọn ọlọkada kọju ija s'awọn ọlọpaa wi pe iya ti wọn fi n jẹ wọn ti pọ ju, ati pe awọn ko le gba a mọ.
 
Wọn ni ṣe ni wọn dana soju opopona kaakiri lati fi f'ẹhonu han s'awọn ọlọpaa, ti wọn si l'awọn ọlọpaa na papa bora.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI