Lara awọn nnkan to ṣe pataki si iṣejọba Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ni igbaye-gbadun araalu, idi ree to fi mu eto ilera lokunkundun l'awọn agbegbe ati igberiko kaakiri ipinlẹ Kwara.
Ile iwosan alabọde to jẹ ti ijọba, eyi to wa nijọba ibilẹ Isanlu Isin n'ijọba tun ti kọ pari bi ẹ ṣe n ka iroyin yii.
Gbogbo awọn ara agbegbe yii patapata ni wọn n dupẹ lọwọ ijọba AbdulRazaq pẹlu ileri to n muṣẹ lasiko lai fi ti ẹlẹyamẹya ṣe.
Ki i ṣe pe ijọba Kwara kan n kọ tabi ṣe awọn atunṣe ile iwosan alabọde yii nikan, ṣe ni wọn n ṣe atunkọ wọn lọna ti yoo ba ti igbalode mu pẹlu awọn irinṣe to poju owo.
Diẹ ree lara awọn fọto ile iwosan alabọde naa.
No comments:
Post a Comment