GBAJUMỌ ỌNỌREBU KU NI KWARA, ỌPỌ AWỌN EEYAN LO BANUJẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, November 16, 2020

GBAJUMỌ ỌNỌREBU KU NI KWARA, ỌPỌ AWỌN EEYAN LO BANUJẸ



Iyalẹnu lọrọ iku ọkan lara awọn aṣoju-ṣofin orilẹ-ede yii tẹlẹ, Ọnọrebu Suleiman Kokori Abdul ṣi n jẹ f'awọn araalu, paapaa awọn ololufẹ ẹ n'igba aye ẹ.
 
Agbegbe Okene/Ogori/Magongo to wa ni ipinlẹ Kwara ni Oloogbe Suleiman Abdul ṣoju fun nile igbimọ aṣoju-ṣofin orilẹ-ede yii nilu Abuja laaarin ọdun 2007 si ọdun 2011.
 
Gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ, opin ọsẹ to kọja yii, iyẹn ọjọ Satide-Abamẹta ni ọkunrin naa jade laye lẹyin aisan rampẹ, ti wọn lo n jẹ ibanujẹ ọkan f'awọn eeyan. Kọmiṣanna tẹlẹri f'ọrọ bi owo ṣe n wọle lọdọ ijọba apapọ, iyẹn Revenue Mobilisation Allocation and Fiscal Commission.
 
Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq nin u atẹjade ibanujẹ rẹ lo ti sọ pe ipa ti oloogbe naa ko laye awọn eeyan, paapaa awọn to ṣoju ko kere rara, ati pe pupọ awọn to ku diẹ kaato fun ni wọn ti jẹ anfaani rẹ.
 
Gomina AbdulRazaq ni ojiji ni iroyin iku Ọnọreebu Suleiman Kokori ba oun, to si dun oun gidi, eyi to ni ajalu nla lo jẹ f'awọn n'ipinlẹ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI