ẸRU KANKAN KO BA MI PE WỌN FẸẸ DA MI DURO - ZIDANE SỌRỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, November 3, 2020

ẸRU KANKAN KO BA MI PE WỌN FẸẸ DA MI DURO - ZIDANE SỌRỌ


Akọnimọ-n-gba ẹgbẹ agbabọọlu Real Madrid, Zinedine Zidane ti sọ pe ko si ẹru kankan lọkan oun wi pe awọn alaṣẹ ẹgbẹ agbabọọlu naa yoo da oun duro bi wọn ko ba bori nibi ifigagbaga ẹgbẹ agbabọọlu naa to fẹẹ waye pẹlu Inter Milan lonii.

Real Madrid ni  wọn wa n'isalẹ tabili ipele keji, iyẹn Group B pẹlu aami kan pere lẹyin ti wọn padanu sọwọ Shakhtar Donesk, ti wọn si tun gba ọọmi pẹlu Burussia Monchengladbach ninu idije Champions League to n lọ lọwọ.

Zidane ni igbaradi fun ifigagbaga naa loun n ṣe lọwọ, oun ko si ronu nnkan mi in ju b'awọn yoo ṣe bori lọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI