Igbesẹ naa bẹrẹ lopin ọsẹ lẹyin ti awọn kan bẹrẹ si n ke pe awọn ọdọ Naijiria lati lọ fopin si idunadura laarin wọn ati ile ifowopamọ naa.
Ṣaaju
ni banki apapọ Naijiria, CBN, ti kọkọ gba aṣẹ lọwọ ile ẹjọ lati kan an
nipa fun awọn ile ifowopamọ pe ki wọn gbẹsẹle apo gbogbo awọn eeyan to
ṣagbatẹru iwọde ọhun.
Lara awọn to ba BBC Yoruba sọrọ sọ pe ko si idi miran ti wọn fi n ti apo wọn ni banki ọhun bi ko ṣẹyin bo sẹ tẹ ẹtọ awọn onibara rẹ loju mọle nitori wọn ṣe iwọde.
Ọkan lara awọn eeyan naa, Allen Olusegun ni "mo maa gbe owo mi kuro nile ifowopamọ Access, mo si maa gbe lọ sile ifowopamọ olokowo kekeke."
Olusegun ni oun ko ni igbagbọ ninu banki naa mọ nitori o le gbẹsẹle owo oun lọjọ iwaju ti oun ba gbiyanju lati ja fẹtọ oun gẹgẹ bi ọmọ Naijiria.
O tẹsiwaju pe ọna ti awọn ọmọ Naijiria le fi sọ fun banki naa pe ohun to ṣe ko dara to ni ki wọn ko owo wọn kuro nibẹ.
O tun sọ pe oun ko ni bojuwẹyin mọ bi banki ọhun ba tilẹ yi ipinu rẹ pada lori awọn apo to tipa.
Ẹlomiran to ti fopin si ibaṣepọ rẹ pẹlu banki Access ṣugbọn ti ko fẹ darukọ ara rẹ sọ fun BBC pe, oun ko owo oun kuro ni banki naa nitori o gbẹsẹle owo awọn oluwọde EndSARS.
Ọkunrin naa ni "mi o lo Access Bank mọ nitori Access bank ti ja ara rẹ kulẹ gẹgẹ ile ifowopamọ, o si tun ja ara rẹ kulẹ niwasju awọn ọmọ Naijiria lapapọ."
O tẹsiwaju pe "to ba jẹ niti emi ni o, Access bank ti di oku si mi, mi o si fẹ ni nnkankan ṣe pẹlu wọn mọ."
Ni ti Farida Adamu, o ni oun ko ni ba banki naa dowopọ mọ nitori bo ṣe fiya jẹ awọn olufẹhonuhan EndSARS lodi si ofin.
Farida sọ pe oun ko ni pada ba banki naa dowopọ lẹyin ti oun ti gbe agadagodo sẹnu apoti oun to wa nileeṣẹ ọhun.
O pari ọrọ rẹ pe "kii ṣe igba akọkọ ree ti banki naa yoo ṣe ohun to lodi si ofin, ti wọn ba si n tẹsiwaju lati maa tẹ ẹtọ awọn onibara wọn loju mọle, o tumọ si pe ko si abo fun owo mi to wa lọwọ wọn."
Ẹwẹ, ninu atẹjade kan ti banki ọhun fi lede loju opo Twitter rẹ, o ni ootọ ni pe oun gbeṣẹle apo awọn awọn onibara oun mẹjọ, ṣugbọn ki ṣe ẹbi oun nitori oun gbọdọ tẹlẹ aṣe banki apapọ Naijiria.
Lati BBC
No comments:
Post a Comment