Ẹ WOJU AWỌN TI WỌN JI GBE LASIKO IRIN-AJO, ORI TI KO WỌN YỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, November 16, 2020

Ẹ WOJU AWỌN TI WỌN JI GBE LASIKO IRIN-AJO, ORI TI KO WỌN YỌ


"Ẹleda mi, o ṣe to o gbabọdi" ladura t'awọn mẹsan kan t'awọn ajinigbe ji gbe loju ọna Kaduna silu Abuja l'ọjọ Aiku-Sanndee ana n gba nigba ti ori ko wọn yọ.
 
Nnkan bi aago mẹta kọja iṣẹju meloo kan la gbọ pe awọn ajinigbe naa ṣina ibọn bolẹ f'awọn to n rin irin ajo loju ọna Kaduna si Abuja, ti wọn si bẹrẹ si i ji awọn eeyan gbe wọnu igbo lọ.
 
Kọmiṣanna fun ọrọ eto aabo abẹle, Ọgbẹni Samuel Aruwwa lo fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ, to si loun dupẹ pe awọn eleto aabo ṣiṣẹ wọn bo ti tọ ati bo ti yẹ.
 
 
O ni nnkan bi aago mẹrin ni iroyin iṣẹlẹ naa to awọn leti, to si loju ẹsẹ l'awọn ti ran awọn eleto aabo lọ lati daabo bo awọn eeyan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI