Afaimọ ni ki wọn ma pada gba iṣẹ lọwọ ọlọpaa kan ti wọn loo muti yo nilu Abuja laipẹ yii, to si mu k'awọn eeyan maa fi ṣẹlẹya kaakiri igboro.
Ohun ti a gbọ ni pe fọnran ọlọpaa naa lo tan kaakiri ori ayelujara laipẹ yii, nibi ti ọlọpaa naa ta a ko mọ orukọ rẹ lasiko ta a kọ iroyin yii tan ti mu ọti yo bamu.
Bi fidio naa ṣe tẹ ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ la gbọ pe wọn ti ranṣẹ pe e lati wa a sọ tẹnu ẹ nipa idi to fi doju ti ileeṣẹ naa nita gbangba.
No comments:
Post a Comment