Ẹ TUN WO OBITIBITI OWO T'IJỌBA APAPỌ FẸẸ FUN IPINLẸ MARUN-UN PERE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, November 24, 2020

Ẹ TUN WO OBITIBITI OWO T'IJỌBA APAPỌ FẸẸ FUN IPINLẸ MARUN-UN PERE


Bi ẹ ṣe n ka iroyin yii, inu idunnu ati ayọ nla l'awọn ipinlẹ marun-un lorilẹ-ede yii, iyẹn Rivers, Bayelsa, Cross-River, Ọṣun ato Ondo wa bayii lori bi ile igbimọ aṣofin ṣe bu ọwọ lu obitibiti owo fun wọn.
 
Owo naa ti wọn pe iye ẹ ni biliọnu mejidinlaadọjọ, iyẹn N148,141,969,161 n'ijọba apapọ sọ pe awọn ṣetan lati da pada f'awọn ipinlẹ naa gẹgẹ bi owo awọn akanṣe iṣẹ ti wọn ṣe lorukọ ijọba apapọ.
 
Lonii ti i ṣe Tusidee ni ile igbimọ aṣofin bu owo lu owo naa lati f'awọn ipinlẹ yii.
 
Igbimọ kan ti wọn gbe kalẹ lati maa ṣe iwadii awọn gbese t'ijọba apapọ jẹ nilẹ yii ati loke-okun lo jabọ naa. Sẹnetọ Clifford Ordia to n ṣoju ẹkun aaringbungbun ipinlẹ Ondo lati inu ẹgbẹ oṣelu PDP ni alaga igbimọ naa.
 
Ordia ninu abajade iwadii naa sọ pe awọn owo yii ni yoo di awọn akanṣe iṣẹ t'awọn ipinlẹ naa ṣe lorukọ ijọba apapọ, to si ni opopona lo pọ ju ninu ẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI