Ọjọ Ajẹ-Mọnde ana ni baale ile kan ti wọn f'ẹsun ijinigbe kan ti f'oju ba ile ẹjọ majisireeti to wa ni Ọta, ipinlẹ Ogun. Ọmọdekunrin, ọmọ ọdun meji la gbọ pe o jigbe.
Adetoro David lorukọ ẹni ọdun mẹrinlelogoji ni wọn pe ẹ. Ọmọ ọdun meji to jẹ ti Ọgbẹni Yẹmi Oluwọle ati iyawo rẹ ni wọn sọ pe David jigbe lagbegbe Oju-Ore to wa ni Ọta
Ẹsun ti wọn fi kan David ni wọn lo tako iwe ofin ọdaran t'ipinlẹ Ogun t'ọdun 2006, to si ni ijiya ninu.
Nigba to n sọrọ, Onidajọ naa, O. L Ọkẹ f'oju aanu wo David, to si ni ki wọn gba beeli ẹ pẹlu ẹgbẹrun lọna igba (200,000) naira pẹlu oniduro meji ti wọn ko jinna si ayika ile-ẹjọ naa, ati pe awọn oniduro naa gbọdọ jẹ awọn to n san owo ori wọn deedee fun ijọba ipinlẹ Ogun.
O wa sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kọkandinlogun oṣu yii.
No comments:
Post a Comment