AYẸYẸ ỌDUN GANNI GBỌNA ARA YỌ, GOMINA ABDULRAZAQ NAA KO GBẸYIN NIBẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, November 8, 2020

AYẸYẸ ỌDUN GANNI GBỌNA ARA YỌ, GOMINA ABDULRAZAQ NAA KO GBẸYIN NIBẸ



Ana ti i ṣe Abamẹta-Satide ni eto ayẹyẹ ọlọdọọdun nni, Gaani t'ilu Kaiama n'ipinlẹ Kwara wa s'opin.
 
Ọna ara ni ayẹyẹ t'ọdun 2020 yii gba yọ pẹlu b'awọn eeyan jankan-jankan to fi mọ Gomina ipinlẹ naa, AbdulRahman AbdulRazaq ko ṣe gbẹyin nibẹ.
 
Lara awọn to tun wa nibẹ ni Ẹmir tilu Kaiama, Alaaji Muazu Shehu Omar; Olori ile igbimọ aṣofin, Ọnọrebu Yakubu Salihu Danlandi; Sẹnetọ Sadiq Umar to n ṣoju ẹkun Kwara North, at'awọn mi in.
 
Oriṣiriṣi aṣa ati iṣẹṣe ni wọn fi d'awọn eeyan lọla, koda ti Gomina AbdulRazaq naa tun jẹri si i pe oun gbadun ara oun kọja sisọ.
 












No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI