Lásìkò tá a kọ ìròyìn yìí tán ni ìjọba orílẹ̀-èdè South Africa ni gbogbo ọ̀nà làwọn yóò gbà lati fi ri i pe ọwọ awọn tẹ gbajugbaja pasitọ kan, Shepherd Bushiri to na papa bora lori ẹsun jibiti ti wọn fi kan an.
Gẹgẹ bi iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ, a gbọ pe odu ni Shepherd Bushiri kaakiri orilẹ-ede South-Africa, ti wọn si lo o pẹlu ọkan lara awọn pasitọ to lowo julọ lagbaye.
Laipẹ yii ni ijọba orilẹ-ede South Africa fi ẹsun jibiti miliọnu mẹfa aabọ dọla ($6.6m) kan, ti wọn si latigba naa ni ọkan ọkunrin naa ko ti balẹ mọ.
Ọsẹ to kọja yii la gbọ pe wọn gbe Bushiri lati fi ọrọ wa a lẹnu wo, ti wọn si fi silẹ pe ko gbada wa a tẹsiwaju lati sọrọ lori ẹsun ti wọn fi kan an naa.
AWIKONKO gbọ pe loju ẹsẹ ti wọn fi ọkunrin yii silẹ lo ti fi orilẹ-ede South-Africa silẹ, to si na papa bora, ko da, wọn ni orilẹ-ede rẹ ti i ṣe Malawi lo salọ.
A tiẹ gbọ pe Aarẹ orilẹ-ede Malawi, Lazarus Chakwera lo lọ fi ọkọ ofurufu t'ijọba pade rẹ lati gbe e kuro ni Suth Africa.
Ṣaaju asiko yii la gbọ pe Bushiri ti sọ pe oun ko mọ nnkankan nipa ẹsun ti wọn fi kan oun, ati pe awọn ti wọn n wa iṣubu oun ni wọn fẹẹ ba toun jẹ, ti wọn si loun lu jibiti aduru owo to to bẹẹ.
Ni bayii, a gbọ pe inu ijọba orilẹ-ede South-Africa ko dun rara bo ṣe gbọ pe Aarẹ ilẹ Malawi lo wa a gbe ọkunrin naa salọ, ti wọn si ni igbesẹ ti n lọ lati ri i pe wọn gbe ọkunrin naa pada lati lọọ jẹjọ ẹsun ti wọn fi kan an.
Pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yii, afaimọ ni ko ma jẹ pe ogun abẹle yoo ṣẹlẹ laaarin awọn orilẹ-ede yii, ti wọn si l'ọkan awọn araalu ko fi tara-tara balẹ lasiko yii.
No comments:
Post a Comment