Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti sọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti ko din ni 432 lọwọ awọn tẹ l'ọdun 2019, to si ni gbogbo wọn ni wọn ti f'oju ba ile-ẹjọ.
Ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Edward Ajogun lo tu aṣiri naa f'awọn oniroyin nilu Abẹokuta lọjọ Iṣẹgun-Tusidee to kọja yii.
Edward ni awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun Aiye ati Ẹyẹ l'awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun tọwọ wọn tẹ, to si l'awọn ṣi tun n wa gbogbo ọna lati rọwọ to awọn yooku.
No comments:
Post a Comment