AYE LE O! ỌBASANJỌ WỌ GAU L'ỌṢUN LẸYIN TI ỌDARAN TO DURO FUN NA PAPA BORA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, November 17, 2020

AYE LE O! ỌBASANJỌ WỌ GAU L'ỌṢUN LẸYIN TI ỌDARAN TO DURO FUN NA PAPA BORA

A ko ri iru eyi ri, a fi n dẹru ba ọlọrọ ni, wọn ni ko si ohun tuntun labẹ ọrun mọ. Bẹẹ gẹlẹ lọrọ ri n'igba ti wọn f'ọju baale ile kan, Adeṣiyan Ọbasanjọ ba ilẹ ẹjọ Majisireeti to wa nilu Oṣogbo, ipinlẹ Ọṣun l'ọjọ Aje-Mọndee ana.
 
Ohun ta a gbọ ni pe, obinrin kan ti wọn pe ni Yeye Bukọla l'awọn ọlọpaa fi ẹsun jibiti kan, ti wọn ni ṣe lo gba owo lọwọ ẹnikan lọna aitọ.
 
A gbọ pe yatọ si eyi, Bukọla tun fi iwe sọwedowo, iyẹn ṣẹẹki lu ẹnikan ni jibiti, ti wọn si ni ẹni naa lo fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa leti. Nigba tọwọ ọlọpaa tẹ Bukọla ni wọn lo o bẹbẹ pe oun yoo da owo naa pada, ti wọn si l'awọn ọlọpaa ni ko lọ mnu oniduro rẹ wa ti ko ba fẹẹ sun atimọle.
 
Idi ree ti wọn lo fi lọ pe Adeṣiyan Ọbasanjọ lati duro f'oun, ti wọn si ni bi wọn ṣe kuro ni teṣan ọlọpaa lọjọ naa ni wọn ti sa kuro nilu Oṣogbọ lọ si ipinlẹ Ogun.
 
Ṣe l'awọn ọlọpaa tọpinpin Ọbasanjọ de ipinlẹ Ogun ko to di pe ọwọ tẹ ẹ, ti wọn si lọ f'oju ẹ ba ile ẹjọ. Wọn ni iwa ti Ọbasanjọ ati Bukọla hu yii tako ofin ọdaran t'ipinlẹ naa t'ọdun 2012, to si ni ijiya nla ninu.
 
Nigba to n sọrọ, Onidajọ A. A. Adeyẹba sọ pe oun yoo fi aaye silẹ lati gba beeli Ọbasanjọ pẹlu owo ti ko din ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta (N500,000) naira ati oniduro meji, to si sun igbẹjọ siwaju d'ọjọ kẹsan oṣu kejila ọdun yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI