Idile ẹlẹsin musulumi ni wọn bi Woli Israel Oladele si. Orukọ abisọ rẹ ni Wasiu. O si jẹ ọmọ ilu Abeokuta, nipinlẹ Ogun.
Awọn obi rẹ pada di ẹlẹsin Kristiẹni, ti wọn si n lọ sinu ijọ kan ni agbegbe Oshodi nipinlẹ Eko.
Gẹgẹ bi akọsilẹ itan igbesi aye rẹ to wa lori ayelujara itakun agbaye ijọ naa, genesisglobal.org, idile ti ko ri ọwọ rọri lo ti wa, nitori oju owo pọn awọn obi rẹ pupọ.
O kiri ọja bi mọin-mọin ati burẹdi, bakan naa lo sẹ awọn iṣẹ pẹẹpẹẹpẹ lati ran awọn obi rẹ lọwọ gẹgẹ bi akọbi.
Iṣẹ ati oṣi to ba awọn obi rẹ finra ko jẹ ko lọ si ileewe tayọ ileewe girama. Koda, ko kẹkọọ pari ti ko fi lọ mọ.
Kilo gbe e de ijọ Celestial?
Itan igbesi aye Wooli Oladele Ogundipe sọ pe idile rẹ ko fẹran ijọ alaṣọ funfun, nigba to wa ni kekere.
Igbagbọ wọn ni pe awọn to n lọ si awọn ijọ naa maa n ṣe oogun, ati awọn nkan ti ko tọ gẹgẹ bi Kristiẹni to jẹ atunbi.
Ijọ Aposteli Kristi, CAC, ni oun ati awọn obi rẹ n lọ. Iwaju ile wọn si ni ile ijọsin naa wa.
O sọ pe awọn kan riran si iya oun nigba to loyun pe ọmọ inu rẹ yoo ṣiṣẹ fun Ọlọrun, amọ iṣẹ alfa tabi imaamu ni awọn obi rẹ n fọkan si nitori ẹlẹsin Musulumi ti wọn jẹ lasiko naa.
Ṣugbọn iṣẹlẹ buruku kan waye ni ọjọ kan.
Iya Oladele jẹ ẹnikan lara awọn obinrin inu ijọ naa ni owo, ti ko si ri i san.
Ni obinrin naa ba wa sile wọn, to si pariwo le iya rẹ lori lati san owo naa.
Ibi ti ariwo ti n waye ni obinrin naa ti ya aṣọ kan ṣoṣo ti iya Oladele maa n wọ jade, mọ ọ lọrun.
Oladele sọ pe iṣẹlẹ naa mu itiju ati ibanujẹ ba oun. Eyi lo si mu ko pinnu lati ma lọ si ṣọọṣi naa mọ, nitori itiju.
Eyi lo mu ko darapọ mọ ijọ Cele kan ti ko jinna si ile wọn.
Gẹgẹ bi ẹni to mọ ilu lilu, Oladele bẹrẹ si ni ba wọn lu ilu ninu ijọ naa.
Kẹrẹ-kẹrẹ, lo ba di ọmọ ijọ Celestial. O ni kii ṣe idaamu, tabi aisan lo gbe oun de inu ijọ alaṣọ funfun.
Nibẹ lo ti bẹrẹ si ni 'gun oke ẹmi', ti ko si ni mọ nkan to n lọ ni ayika rẹ fun bi ọjọ meje, lai mu omi tabi jẹun, to si sọ n sọ asọtẹlẹ.
O si ti n ṣiṣẹ alufaa ijọ Cele fun ọdun mẹrinla gbako.
Afojusun rẹ si ni lati da yatọ si awọn ijọ Cele yooku, nipa iwaasu ati isẹsi wọn.
Ǹkan mẹ́wàá tí ẹ ò gbọ́ rí nípa Israel Oladele, Woli ìjọ Genesis Global
Israel Oladele Ogundipe (GENESIS) ni oludari ati alakoso ijọ Celestial Church of Christ, Genesis Global, ọkan ninu awọn ẹni ifami ororo yan tawọn ololufẹ rẹ n warii fun gẹgẹ bí ajinrere fun ijọ CCC lagbaye.
Olusọaguntan ni pẹlu, ó jẹ olukọ ati onisesẹ Aposteli.
Ọmọ ilu Igboore ni ilu Abeokuta ipinlẹ Ogun ni woli Israel Oladele ṣugbọn ọmọ atapata dìde ni to si jẹ iya ki o to de ipo to wa.
Ẹni ọdun marundinlaadọta ni Israel Oladele Ogundipe.
Ǹkan mẹ́wàá tí ó yẹ kí ó mọ̀ nípá Woli Genesis
Wasiu ni orukọ abisọ rẹ nitori idile Musulumi ni a ti bi i, o fi aye rẹ fun Jesu Kristi o si n lọ ijọ Christ Gospel Apostolic Church nibi to ṣi n lọ di asiko yii, Diakoni ni baba ati iya rẹ ninu ijọ CGAC.
L'owurọ ọjọ rẹ, o wu u lati lọ si fasiti ki o lọ gboye ẹkọ isiro owó, ṣugbọn ko wa si imuṣẹ nitori awọn obi rẹ ko lowo lati ran an lọ, o tun wọ Fasiti Obafemi Awolowo ṣugbọn ko ri owo ile iwe san mọ lo fi kuro ti ko ka a pari.
Loni Oladele Ogundipe lo ń dari dari ìjọ Celestial to pọ julọ lagbaye pẹlu ọmọ ìjọ to to ẹgbẹrun mẹta ninu isin kan ṣoṣo.
O ti dabi awokose fun ọpọ awọn alakoṣe ìjọ Celestial, ti ipinu ọpọ eniyan si ti yipada nipa iṣe ati ihuwasi awọn Celestial, o yi ilana iwaasu aye lailai padà nípa ẹbun ikọni, wooli, ajihinrere ati ẹbun ṣiṣe oju aanu fawọn eeyan to ni.
O ti koju oniruuru ipenija paapaa julọ lasiko to n dagba ati irú idile to tí wa to fi mọ nipa ibaṣepọ ṣaaju igbeyawo.
Wooli Oladele ti ṣe olootu oniruuru awọn eto lori mohunmaworan àti Redio jakejado orile-ede Naijiria.
Ohun ni oludasile àti aarẹ Genesis Leadership Academy, nibi to tin kọ awọn ọdọ bi a ṣe n dipo adari mu. Ajọ ti kii ṣe ti jọba to dasilẹ kii ṣe lati pawo nitori pe o ni gbagbọ pe iṣoro ti o wa nilẹ niṣe pẹlu iru olori to wa niluu.
Ọdun 2012 ni o da ileẹkọ imọ nipa adari silẹ, bakan naa lo ni ajọ ti kii ṣe ti ijọba miran to n jẹ Israel Oladele Ogundipe Foundation oun si ni aarẹ ajọ naa. O da a silẹ lati maa ran awọn alaini lọwọ nitori bi idile rẹ ṣe talaka nigba to wa ni kekere.
O jẹ onkowe ati ontẹwe, alaga ile itẹwe ISOLAD.
No comments:
Post a Comment