Awon ti ko din ni ogun la gbọ wi pe wọn dagbere faye nibi ijamba mọto to ṣẹlẹ l'ọja kan to gbajumọ daadaa n'ipinlẹ Ondo, ,iyẹn ọja Akungba Akoko to wa n'ijọba ibilẹ Akoko South-West lopin ọsẹ to kọja yii.
Ni nnkan bi aago meje aabọ irọlẹ ọjọ Satide-Abamẹta ni ijamba naa waye nigba ti wọn sọ pe tirela kan to n ko irẹsi lọ ni ijanu rẹ deede da iṣẹ silẹ lori ere, to si yawọ inu ọja naa, nibi to ti f'ẹmi awọn eeyan ṣofo danu.
Awọn ti ko din ni ogun la gbọ pe jẹ ipe Ọlọrun loju ẹsẹ, n'ibi t'ọpọ awọn eeyan ti farapa kọja sisọ.
Agbẹnusọ awọn ọlọpaa n'ipinlẹ naa, Ọgbẹni Tee Leo Ikoro f'idi iṣẹlẹ naa mulẹ wi pe lootọ ni. Amọ ṣa, kaakiri ipinlẹ Ondo l'awọn eeyan ṣi n sọrọ lori ijamba buruku naa titi di asiko ta a kọ iroyin yii tan.
No comments:
Post a Comment