Irọlẹ ana ti i ṣe Tọside la gbọ pe awọn adigunjale ya wọ banki kan to wa nilu Ode-Irele to wa nijọba ibilẹ Irele, ipinlẹ Ondo, ti wọn si ji obitibiti owo ko nibẹ.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, wọn ni nnkan bi aago mẹrin irọlẹ l'awọn adigunjale naa yawọ ilu Irele, ni ko pẹ ti ọga ọlọpaa orilẹ-ede yii ṣabẹwo si olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa.
Fun bi i iṣẹju marunlelogoji la gbọ pe wọn fi ṣiṣẹ naa, ko to di pe wọn ba ti wọn lọ, ti wọn si ji obitibiti owo ko nibẹ.
Agbẹnusọ awọn ọlọpaa ipinlẹ naa, Tee-Leo Ikoro f'idi iṣẹlẹ naa mulẹ, to si ni iwadii ti bẹrẹ.
No comments:
Post a Comment