ÀṢÍRÍ BI WỌN ṢE TA ILEEṢẸ OMI N'IPINLẸ KWARA FI KỌ́ ILÉ-EPO TU SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, November 10, 2020

ÀṢÍRÍ BI WỌN ṢE TA ILEEṢẸ OMI N'IPINLẸ KWARA FI KỌ́ ILÉ-EPO TU SITA


Àná tí í ṣe Ọjọ́ Ajé, ìyẹn Mọnde ni igbimọ tí Gómìnà ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq gbé kalẹ láti ṣe ìwádìí báwọn ìjọba tó kọjá ṣe tá àwọn ohun ìní ìjọba lọ́nà tí kò bá òfin mú bẹ̀rẹ̀. 

Púpọ̀ àwọn aráàlú àtàwọn tí ọ̀rọ̀ kan ni wọn wá níbẹ̀ láti wo bí nnkan ṣe ń lọ sí, kódà táwọn èèyàn tún dìde láti jẹ́rìí sáwọn ohun tí mọ báwọn kan ṣe tá dúkìá ìjọba nitakuta. 

Níbi ètò náà ni àṣírí tí jáde síta wí pé àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba kan tá lára dúkìá ìjọba, ìyẹn ilẹ̀ to je ti ileeṣẹ olómi, ìyẹn Water Corporation tó wà ní Olalomi Water Reservoir lójú ọna Ira, ìlú Ọ̀ffà. 

Abẹ ìṣàkóso Gómìnà Abdulfattah Ahmed là gbọ pé wọn tí tá lára ilẹ̀ náà. 

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀, Òṣìṣẹ́ fẹyinti ń'ileeṣẹ ìjọba tó ń rí sọ̀rọ̀ ilẹ̀, Ọgbẹni Samuel Ajide sọ pé ọdún 2015 lòun gbọ pé ìjọba fẹẹ tá lára ilẹ̀ ileeṣẹ Olómi náà, tó sì ni oṣù kẹwàá ọdún 2015 ni obìnrin kan tí wọn pé ni Alaaja Bintu Lawal yọjú wí pé òun nífẹ̀ẹ́ sì láti ra ilẹ̀ náà, àti pé ilé-epo lòun fẹẹ fi kọ. 

Ó ni miliọnu méje náírà ni Alaaja Lawal san sínú àpò owó ilé ifowopamọsi òun, tó sì ni oríṣiríṣi akanti àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ni wọn san èyí tó pọ̀ ju nínú owó náà sì í. 

Ajide ni ìyàlẹ́nu lo jẹ́ foun pé wọn bu ọwọ lu ilé èpò lórí ilẹ̀ náà, èyí tó lo tako ìdí pàtàkì kí wọn fi gbé títa ilẹ̀ náà síta. 

Ó nígbà tí wọn kò tètè fẹẹ gbé ilẹ̀ náà fún Alaaja Lawal lo mú kó sáré gba ọdọ Ọnọrebu Hassan Oyeleke to jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ilẹ̀ igbimọ aṣofin ipinlẹ náà tẹ́lẹ̀ lọ, tó sì nibẹ ni wọn parí ọ̀rọ̀.

Alaaja Lawal tí wọn loo ra ilẹ̀ náà nínú ọ̀rọ̀ rẹ sọ pé irọ́ ni Ọgbẹni Ajide pá mọ òun, torí pé Ajide fúnra rẹ lo fi ilẹ náà lu òun ni jìbìtì miliọnu méje náírà. 

Òní tí í ṣe Tusidee ni ìjókòó igbimọ náà yóò tún padà wáyé. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI