Pẹ̀lú ìbínú làwọn ara agbègbè kan n'ilu Onitsha, ipinlẹ Anambra fi dáná sún tirela ileeṣẹ Dangote kan tí wọn loo tẹ alabaru pá laarọ àná, ọjọ́ Iṣẹgun tí i ṣe Tusidee.
Nnkan bí aago mẹ́wàá kú ìṣẹ́jú márùn-ún là gbọ pé ṣe ni tirela Dangote náà sáré kúrò lójú ọ̀nà rẹ, tó sì lọọ tẹ ọkùnrin alabaru náà tí wọn koo gbajumọ dáadáa lágbègbè náà.
Itosi Banki kan tí wọn pé ni Zenith to wá lopopona Onitsha sì Owerri ni ìjàmbá burúkú náà tí wáyé.
Lójú ẹsẹ̀ tí wọn ní ijamba náà tí wáyé là gbọ pé awakọ náà tí pòórá, tí kò sì sẹni tó lè sọ bo ṣé pòórá, èyí gan án lo tún bí àwọn èèyàn nínú pupọ tí wọn fi dáná sún tirela náà.
Ọgbẹni Kamal Musa to jẹ́ oludanilẹkọọ fidihẹ fún àjọ ẹṣọ ojú popona, ìyẹn FRSC fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ sọ pé àwọn òṣìṣẹ́ wọn ní wón sáré debẹ láti pẹtu sáwọn ọdọ tí inú ń bí náà nínú, kò tó di pé wọn gbé òkú náà lọ sí mọṣuari.
Nínú ìròyìn mi in tó fara pẹ ẹ là tí gbọ pé tirela ńlá kan tí tẹ ṣọja pá lásìkò tí wọn ní ṣọja náà ń gbìyànjú láti gba ẹgbẹ tirela yìí kọjá.
Ibudokọ kan tí wọn pé ni Ikot Ansa to wá lójú ọna Murtala Mohammed n'ijọba ìbílẹ̀ Calabar Municipality niṣẹlẹ náà tí wáyé ní nǹkan bí aago méje kọjá ìṣẹ́jú márùndinlọgbọn ọjọ́ Mọnde ijẹta.
No comments:
Post a Comment