ZULUM TU AṢIRI B'AWỌN ṢỌJA ṢE LE ṢẸGUN BOKO HARAM SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, October 7, 2020

ZULUM TU AṢIRI B'AWỌN ṢỌJA ṢE LE ṢẸGUN BOKO HARAM SITA


Gomina ipinlẹ Borno, Ọjọgbọn Babagana Zulum ti tu awọn aṣiri nla sita nipa bi ileeṣẹ ologun orilẹ-ede yii ṣe le ṣẹgun awọn Boko Haram, ti wọn yoo si d'ohun igbagbe patapata, o wa a ku si ijọba lọwọ lati tẹle e.

Zulum sọ pe lara awọn ọna ti ileeṣẹ ologun fi le gbogun ti awọn Boko Haram ti wọn n fojoojumọ da ẹmi awọn eeyan legbodo ni pe lati dẹkun ọna ti wọn fẹẹ gba lati kọkọ gbogun jade.

Nibi eto oloṣu mẹta-mẹta ti ileeṣẹ ọga ologun maa n ṣe, eyi ti wọn ṣe mẹta rẹ papọ nilu Maiduguri lana ni Gomina Zulum ti daba yii pe bi wọn ba n fẹ alaafia, afi ki wọn ṣetan, ki wọn si mura giri lati koju awọn Boko Haram naa.

O ni ko yẹ k'awọn ologun maa duro de igba t'awọn Boko Haram ba ṣọṣẹ ki wọn to o dide lati sọ pe awọn fẹẹ gbẹsan, bi ko ṣe pe k'awọn naa dide lati wa gbogbo ibi ti wọn ba n farapamọ si kan, ki wọn si gbogun ti wọn nibẹ.

Nibẹ lo ti wa a sọ pe lara awọn eto t'oun ni nilẹ f'awọn araalu, paapaa nipa eto aabo ni pe oun yoo f'awọn eeyan oun l'ọkan balẹ, ati pe gbogbo nnkan to ba wa nikawọ oun loun yoo ṣe lati ran ileeṣẹ ologun lọwọ, ki wọn le tete ṣẹgun awọn Boko Haram naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI