WỌN JÙ ABẸL S'Ẹ́WỌ̀N ỌDÚN MÁRÙNLÉLỌ́GỌ́FÀ NÍTORÍ JÌBÌTÌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, October 1, 2020

WỌN JÙ ABẸL S'Ẹ́WỌ̀N ỌDÚN MÁRÙNLÉLỌ́GỌ́FÀ NÍTORÍ JÌBÌTÌ


Ohun tó dájú dáadáa ní pe ẹ̀wọ̀n gbere ni wọn ju Allen Abel sì, kí í ṣe ẹ̀wọ̀n tí yóò tètè lọ, tí yóò sì sáré padà dé. 

Ẹ̀wọ̀n ọdún márùnlélọ́gọ́fà {125} ni wọn ju Allen Abel sì lórí ẹ̀sùn jìbìtì owó tó dín díẹ̀ ni miliọnu mẹ́tàlá, ìyẹn N12.8m náírà.

Ile ẹjọ́ gíga kan tó wà nipinlẹ Borno ni wọn ti gbé ìdájọ́ náà lè Allen lọ́wọ́ wí pé kò lọ gbádùn ayé rẹ yòókù lọgba ẹ̀wọ̀n. 

A gbọ pé ayédèrú eto oúnjẹ ọ̀fẹ́, ní Allen àti àwọn kan tí wọn pé ní Suleman Ádámù, Usman Ádámù fi lu ileeṣẹ ìjọba tó ń rí sọ̀rọ̀ àjálù lórílẹ̀ èdè yìí, ìyẹn Federal Ministry of Humanitarian Affairs, Disaster Management and Social Development (FMHDSD)’s School Feeding scheme lábẹ́ àkóso Social Intervention Programme (SIP) tí ìjọba àpapọ̀ ni jìbìtì 

Ileeṣẹ kan tí wọn pé ní Lelle Hyelwa Sini of Lelle Foresight Construction Co. Ltd la gbọ pé wọn fi lu jìbìtì náà, tí àṣírí sì padà tú síta. 

Bí àṣírí ṣe tú s'ọwọ àjọ EFCC ni wọn ti fojú rẹ bá ilé ẹjọ́ lọ́jọ́ kejì oṣù keje ọdún yìí, kò tó di pé ìdájọ́ wáyé lànà tí í ṣe Ọjọru, Wẹside.

Onidajọ Kumaliya lo dá ẹjọ́ náà pé àwọn esun ogún ọ̀hún ni wọn ní iye ọdún wọn, tí apapọ àwọn ọdún náà sì jẹ márùnlélọ́gọ́fà. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI