Eeyan kan l'awọn tọọgi gun n'igo nibudo idibo kan to wa nilu Akurẹ, ipinlẹ Ondo lonii ti eto idibo gomina nlọ lọwọ.
Wọọdun kẹrin, uniiti keji to wa ni Ijomu, ijọba ibilẹ Akurẹ South n'iṣẹlẹ naa ti waye, ti igbakeji Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ naa, Ọgbẹni Lanre Bankọle si f'idi rẹ mulẹ pe loootọ ni.
Bankọle ni eeyan meji lọwọ ti tẹ lori bi wọn ṣe gun ọkunrin naa, to si ni wọn ti wa lahamọ awọn, ati pe wọn ti gbe ọkunrin naa lọ si ọsibitu nibi to ti n gba itọju lọwọ.
No comments:
Post a Comment