L'ọjọ Iṣẹgun-Tuside to kọjá yìí ni ile ẹjọ gíga tó wà ní Ikẹja n'ilu Èkó dá ẹjọ ikú fún obìnrin ẹni ọdún mẹ́rìndínlógójì kan, Stella Gilbert lórí ẹ̀sùn ipaniyan.
Wọ́n ni ṣe ni Stella gùn ọkàn lára àwọn tí wọn jọ ń gbé inú ilé kan náà tó wà lágbègbè Ajegunlẹ n'ilu Eko pá, ìyẹn Stella Godwin.
Ibi tí wọn tí ń fà ọ̀rọ̀ tí kò tó nnkan là gbọ́ pé Stella Gilbert tí gùn ẹni náà pá, táwọn èèyàn sì lọ fà á lé ọlọ́pàá lọ́wọ́.
Ṣe ni Stella dákú nígbà tó gbọ ìdájọ́ ikú náà, ṣùgbọ́n táwọn òṣìṣẹ́ ọgbà ẹwọ̀n sáré gbé e, tí wón sì lọ fi pamọ di ọjọ́ ikú rẹ.
No comments:
Post a Comment