ỌPẸ Ó! ÌJỌBA SAUDI ARABIA TI ṢÍ MẸKA SÍLẸ̀ FÚN UMURAH - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, October 30, 2020

ỌPẸ Ó! ÌJỌBA SAUDI ARABIA TI ṢÍ MẸKA SÍLẸ̀ FÚN UMURAH


Ìjọba orílẹ̀-èdè Saudi Arabia tí kéde ọjọ́ Ajé, Mọnde ọ̀sẹ̀ to ń bọ̀ gẹ́gẹ́ ọjọ́ tí gbogbo àwọn ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí káàkiri àgbáyé yóò láǹfààní láti wọ ìlú Mẹ́kà fún Umurah. 

Ileeṣẹ tẹlifiṣan Saudi Arabia, Al-Arabiya ló gbé ìròyìn náà síta, èyí tó mú kí àwọn Mùsùlùmí bẹ̀rẹ̀ si í fò fún ayọ̀. 

Lati nnkan bí oṣù kejì ọdún yìí ni wọn ti kéde títì pá Mẹka láti dẹkun itankalẹ àrùn COVID-19 fáwọn èèyàn lagbaye, tó sì jẹ pe oṣù kẹta ni wọn fi òfin de àwọn ọmọ ìlú náà láti máa kópa. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI