Loni ni ileeṣẹ ọlọpaa tu awọn ọlọpaa kogberegbe, iyẹn SARS ka, lẹyin ọpọlọpọ ẹsun iwa ibajẹ t'awọn araalu fi kan wọn.
Ohun ta a gbọ ni pe ọga ọlọpaa patapata lorilẹ-ede Naijiria, Mohammed Adamu lo pe ipade awọn oniroyin, nibi to ti kede sita wi pe oun tu ẹka ileeṣẹ ọlọpaa kogberegbe naa ka gẹgẹ b'awọn araalu ṣe n fẹ.
Bi wọn ṣe pari ipade naa tan ni olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa nilu Abuja la gbọ pe ọkan lara awọn oniroyin to jẹ ti ileeṣẹ Arise Tẹlifiṣan, Ogbonna Francis jade sita.
Bo ṣe jade lati maa lọ ni wọn lo o pade awọn kan ti wọn n fẹhonu han, to si gbiyanju lati fọrọ wa wọn lẹnu wo nipa nnkan ti wọn ri si igbesẹ tuntun naa.
Ibi to ti n fọrọ wa wọn lẹnu wo la gbọ pe awọn ọlọpaa ti ya bo wọn, ti wọn si bẹrẹ si i lu wọn.
Ibi ti wọn ti n lu wọn la gbọ pe wọn ti fọ idi ibọn mọ Ogbonna lori, ti ẹjẹ si bẹ jade lori ẹ.
No comments:
Post a Comment