Pasitọ ti ẹ n wo yii lo tun tan kaakiri ikanni ayelujara lasiko yii, lori bi fido ibi to ti n fa irun abẹ awọn obinrin inu ṣoọọṣi ẹ, to si ni iṣẹ iyanu nla loun fi n ṣe e.
Orilẹ-ede Ghana lọhun la gbọ pe Pasitọ yii ti a ko ti i mọ orukọ ta a fi kọ iroyin yii tan wa, pupọ awọn ọmọ ijọ lo si ni, to maa n ṣe iṣẹ
idan to n pe ni iyanu fun wọn.
A gbọ pe awọn obinrin lo pọ ninu ṣọọṣi, iyẹn awọn ti wọn n wa iyanu ojiji.
Nibi ti wọn ni Pasitọ naa ti n sọrọ lo ti sọ fun gbogbo awọn to wa ni ṣọọṣi ẹ pe ki wọn yọ foonu wọn sita lati maa fi ya aworan nnkan toun n ṣe, ki iroyin ma ba a jade sita wi pe oun n bọ pata awọn obinrin.
Oriṣiriṣi l'awọn eeyan ti n sọ nipa pasitọ naa bayii.
No comments:
Post a Comment