LẸYIN OṢU MỌKANLA, WỌN JU WOLII SỌTITOBIRẸ S'ẸWỌN GBERE PẸLU IṢẸ AṢEKARA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, October 6, 2020

LẸYIN OṢU MỌKANLA, WỌN JU WOLII SỌTITOBIRẸ S'ẸWỌN GBERE PẸLU IṢẸ AṢEKARA


Ariwo 'Haaaaaaaaa' lo gba ẹnu awọn ero kọọtu giga t'ipinlẹ Ondo to wa nilu Akurẹ lonii n'igba ti wọn ju gbajumọ wolii kan, Wolii Babatunde Alfa s'ẹwọn gbere pẹlu iṣẹ aṣekara.
 
Onidajọ Oluṣẹgun Oduṣọla lo ṣe idajọ naa lonii lori ẹsun meji ọtọọtọ to ni i ṣe pẹlu ipaniyan ati ijinigbe.
 
Bẹ o ba gbagbe, Wolii Babatunde Alfa ni oludasilẹ ṣọọṣi Sotitobire Praising Chapel n'ibi ti ọmọdekunrin, ọmọ ọdun kan, Kọlawọle Gold ti poora lasiko isin, iyẹn ọjọ kẹwaa oṣu kọkanla ọdun to kọja.
 
Lẹyin ti wọn wa ọmọ naa titi ti wọn ko ri i lo mu ki wọn fẹsun rẹ kan Wolii Alfa wi pe o mọ nipa bọmọ naa ṣe poora, ti wọn si gbe e latigba, ko to di pe wọn f'oju rẹ ba ile-ẹjọ.
 
Bi ẹjọ naa ṣe n lọ lọwọ l'awọn ẹlẹri loriṣiriṣi ti n yọju lati tako Wolii naa, eyi to mu ki Onidajọ naa sọ pe awọn ẹri to wa niwaju oun kọja nnkan teeyan le maa f'ọwọ bo m'ọlẹ, to si ni ko lọ lo eyi to ku n'igbesi aye rẹ l'ọgba ẹwọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI