LẸYIN OṢU MEJE TO BIMỌ TAN, BLESSING KO RI OWO ỌSBITU SAN L'EKOO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, October 2, 2020

LẸYIN OṢU MEJE TO BIMỌ TAN, BLESSING KO RI OWO ỌSBITU SAN L'EKOO


Ẹgbẹrun marundinlọgọrun pere ni obinrin kan to ṣẹṣẹ bimọ l'ọsibitu Mojol to wa ladugbo Churc, Shasha n'ipinlẹ Eko jẹ, ti wọn ko si fi silẹ lọ sile rẹ nitori owo naa.

Lati nnkan bi oṣu meje sẹyin la gbọ pe Blessing Bassey ti bimọ ọwọ ẹ, ti wọn si l'awọn oṣiṣẹ ọsibitu naa ko fi silẹ lati maa lọ sile nitori owo ti ko ri san.

Ọsibitu naa ni wọn sọ pe Blessing, ọmọ ọdun mẹtadinlọgbọn naa n sun si pẹlu ọmọ rẹ, ibẹ si lo ti n ṣe gbogbo nnkan to yẹ ko ṣe.

Ilẹẹlẹ ọkan lara awọn wọọdu inu ọsibitu naa ni Bleesing n sun si pẹlu ọmọ rẹ, to si n duro de ọjọ ti yoo ri owo to jẹ san lati maa lọ silẹ.

Ki i ṣe Blessing ko ni ọkọ to bimọ fun rara, ṣugbọn gbogbo ipa ati agbara ti ọkọ Blessing sa lati ri owo naa san lo ja si pabo titi ta a fi pari iroyin yii.

Blessing ninu ọrọ rẹ sọ pe lọjọ kẹfa oṣu kẹta ọdun yii loun daku, ti wọn si sare gbe oun wa si ọsibitu naa, ọjọ naa lo sọ pe wọn sare ṣiṣẹ abẹ f'oun lati doola ẹmi oun ati t'ọmọ oun.

O ni latigba naa l'awọn ko ti ri owo itọju ti wọn ṣe f'oun san, nitori pe ẹgbẹrun lọna ọọdunrun naira ni wọn beere lẹyin iṣẹ abẹ naa, ṣugbọn to ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun naira pere l'awọn ri san.

Lẹyin ẹ lo l'awọn tun wa owo naa, t'awọn si tun san ẹgbẹrun marundinlọgọta naira, t'awọn ko si ti i ri eyi toku san.

Alakoso ọsibitu naa, Salami Akindayọ n'igba toun naa n sọrọ sọ pe iru nnkan bẹẹ ti ṣẹlẹ ri, ṣugbọn to ni ṣe ni ẹni naa salọ, t'awọn ko si ri i, idi ree to l'awọn ko ṣe fi Blessing silẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI