KWARA: ÀWỌN AKẸ́KỌ̀Ọ́ PADÀ SILE-ẸKỌ LÁRA-Ọ̀TỌ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, October 1, 2020

KWARA: ÀWỌN AKẸ́KỌ̀Ọ́ PADÀ SILE-ẸKỌ LÁRA-Ọ̀TỌ̀


Ọjọ́ karùn-ún oṣù yìí ni gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ pátápátá káàkiri ìpínlẹ̀ Kwara yóò padà sẹnu ẹ̀kọ́ wọn gẹ́gẹ́ bo ṣé wá tẹ́lẹ̀, nígbà táwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga yóò padà sẹnu ẹ̀kọ́ tiwọn lọ́jọ́ kejìlá oṣù yìí bákan náà. 

Kọmiṣanna fún ètò ẹ̀kọ́ nipinlẹ náà, Ọnọrebu Harriet Afọlabi-Oshatimẹhin lo fìdí rẹ múlẹ̀ laipẹ yìí wí pé ètò ẹ̀kọ́ yóò bẹ̀rẹ̀ ni pẹrẹu ni ìbámu pelu alakalẹ ìdẹkùn ìtàn kalẹ ajakalẹ àrùn Covid-19. 

Afọlabi-Oshatimẹhin jẹ́ kó di mímọ̀ pé ohun tó dájú pé gbogbo àwọn olùkọ́ ni wọn ti gba idanilẹkọọ to péye lórí ọna ti wọn yoo gba ṣiṣẹ wọn, èyí tí yóò dẹkùn ajakalẹ àrùn náà. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI