Ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun lábẹ́ Gómìnà Dapọ Abiọdun tí kéde wí pé kí gbogbo ilé ẹ̀kọ́ káàkiri ipinlẹ náà padà sẹnu ẹ̀kọ́ wọn bo ṣe wá tẹ́lẹ̀.
Lati nnkan bí oṣù mélòó kan sẹ́yìn ni ìjọba tí kéde pé kí ètò ẹ̀kọ́ wá ní ségesège láti dẹkun itankalẹ ajakalẹ àrùn koronafairọọsi.
Ṣùgbọ́n ní báyìí, ìjọba ipinlẹ Ogun tí sọ pé bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ Ajé, Mọnde ọ̀sẹ̀ to ń bọ̀, ìyẹn ọjọ́ kejì oṣù kọkànlá.
Ninu atẹjade tí akọ̀wé ìròyìn Gómìnà, Ọgbẹni Kunle Ṣomọrin fi síta lo tí sọ pé ajakalẹ àrùn tí dínkù dáadáa ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, ìdí èyí ló ní Gomina pàṣẹ pé kí eto ọ̀rọ̀ aje padà sí bo ṣe wá tẹ́lẹ̀.
No comments:
Post a Comment