KO SI KỌMU MI L'ỌJA IPATẸ NAIJIRIA, ẸGBẸRUN MẸẸDOGUN NI WỌN N TA A NILU OYINBO - ANTI RẸMI PARIWO SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, October 29, 2020

KO SI KỌMU MI L'ỌJA IPATẸ NAIJIRIA, ẸGBẸRUN MẸẸDOGUN NI WỌN N TA A NILU OYINBO - ANTI RẸMI PARIWO SITA


Gbajugbaja oṣerebinrin nni, Oluwarẹmilẹkun Faith Fatolu ti sọ ọkan pataki lara nnkan to maa n jẹ ẹdun ọkan fun un, to si ni nnkan naa maa n ba oun lọkan jẹ gidigidi.
 
Ki lẹ lero wi pe o le maa jẹ ẹdun ọkan fun gbajumọ oṣerebinrin to tun rẹwa, t'awọn ololufẹ rẹ si tun n gba tiẹ gidigidi?
 
Ọmu ni o. Ọrọ Yoruba kan to sọ nipa 'Ajao', eyi ti wọn ni apa rẹ gun ju itan lọ naa lo n ṣẹlẹ si Rẹmilẹkun Fatolu bayii.
 
"Ti wọn ba ti debẹ tan. Aa wa di pe ẹyin lẹ ma maa wa wọn kiri to dẹ jẹ pe awọn lo n lee yin kiri nigba ti wọn o tii debẹ".

Anti Rẹmi Ọlọyan nla sọ iriri rẹ gẹgẹ bi ẹni ti ọyan ẹ tobi gan, ati ohun toju rẹ maa n ri pẹlu awọn ọkunrin oloju-komu-o-lọ.

Oṣere ni Oluwarẹmilẹkun Faith Fatolu, ṣugbọn ti awọn ololufẹ rẹ maa n pe ni Anti Rẹmi.

Ko si ile itaja kọmu to wa ni orilẹ-ede Naijiria ti Anti Rẹmilẹkun ko ti i de lati wa iru kọmu ti yoo ba ọmu rẹ mu, ṣugbọn to jẹ pabo lo maa n ja si fun un.
 
Anti Rẹmi ki i ri iwọn kọmu rẹ ra l'ọja, to si jẹ nigba ti yoo ba ri i, ṣe lowo rẹ maa n lọ soke ju awọn yooku lọ, to si ni ilu Oyinbo loun ti maa n ri kọmu ra nipasẹ awọn ọrẹ rẹ.
 
Fidio naa ree: Anti Rẹmi

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI