Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq ti sọ pe ko s'ohun meji to mu ki Gomina ipinlẹ Ondo, Arakunrin Ọluwarotimi Akeredolu jawe olubori lẹẹkeji bi ko ṣe ti awọn iṣẹ rere to ti ṣe silẹ ni saa akọkọ rẹ.
Ọrọ yii waye ni kete ti ajọ eleto idibo kede Gomina Akeredolu gẹgẹ bi gomina lẹẹkeji n'ipinlẹ naa lẹyin to jawe olubori nibi eto idibo to waye lopin ọsẹ to kọja lọ yii.
Gomina AbdulRazaq sọ pe iṣakoso ọdun mẹrin Gomina Akeredolu n'ipinlẹ Ondo ko ṣee fọwọ rọ sẹyin lẹka eto idagbasoke ipinlẹ naa, eyi to mu k'awọn eeyan jade lọpọ yanturu lati dibo fun lẹẹkeji.
Bẹẹ lo gbe oriyin f'awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC n'ipinlẹ Ondo lori iṣẹ takuntakun ti wọn ṣe lati ri i pe ipo Gomina ko bọ mọ wọn lọwọ.
No comments:
Post a Comment