GBAJUMỌ WOLII IJỌ SẸLẸ TO N LU JIBITI KAAKIRI DERO ATIMỌLE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, October 7, 2020

GBAJUMỌ WOLII IJỌ SẸLẸ TO N LU JIBITI KAAKIRI DERO ATIMỌLE


Atimọle ọlọpaa ni gbajugbaja Wolii ijọ sẹlẹ kan, iyẹn Celestial Church of Christ, ẹka ti Marvelous Model Parish to wa n'ilu Ọbada-Oko, ipinlẹ Ogun, Wolii Oluwakẹmi Ṣotọnọde wa bi ẹ ṣe n ka iroyin yii lori ẹsun jibiti.

Oluwakẹmi t'awọn eeyan tun mọ si Marvelous la gbọ pe awọn ọlọpaa ti n wa lati ọdun to kọja lẹyin ti ọkunrin, Idris Ilyas f'ẹsun jibiti kan an.

AWIKONKO gbọ pe ọjọ kọkanla oṣu kọkan ọdun to kọja lo pe Idris pe ko ba oun ko okuta kan Kaolin lo si ileeṣẹ kan, lẹyin ti Idris ko awọn okuta naa ni wọn sọ pe Oluwakẹmi lo gba owo okuta naa lẹyin.

Owo naa ti wọn ni miliọnu kan ati ẹgbẹrun lọna igba (N1.2m) naira ni wọn sọ pe Oluwakẹmi gba, to si na papa bora.

Lẹyin ẹ ni wọn lo o tunfi ilẹ lu Ọlabangboye Ọlalekan ni jibiti, to si gba ẹgbẹrun lọna igba (200,000) naira lọwọ ẹ ko to tun na papa bora, iyẹn l'oṣu kẹsan an to kọja yii.

Ṣaaju asiko yii ninu oṣu kẹrin ọdun yii la gbọ pe o tun fi okuta Kaolin naa lu Kẹhinde Ọjẹkunle ni jibiti ẹgbẹrun lọna ọọdunrun (300,000) naira. Wọn ni bo ṣe ṣe fun Idris lọdun to kọja naa lo tun ṣe fun Kẹhinde, ti wọn si latigba to ti lọ gba owo lẹyin lo ti juba ehoro.

Bakan naa ni nu oṣu kẹta ọdun yii lo tun lu Gbọlagade Damilọla ni jibiti N670,000 naira. Wọn ni irẹsi baagi ogoji lo sọ pe oun fẹẹ ta fun Gbọlagade, ti wọn si latigba to ti gba owo naa ni wọn ko ti ri i mọ.

Awọn ẹsun yii lo tẹ ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ lọtọọtọ, ṣugbọn ti aṣiri rẹ pada tu sita.

Ana ti i ṣe Tuside lọwọ tẹ  Oluwakẹmi nibi to sapamọ si. Awọn kan la gbọ pe wọn ta awọn ọlọpaa lolobo ti wọn fi ri i mu.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Edward Awolọwọ Ajogun ti sọ pe Oluwakẹmi ṣi wa lahamọ awọn nibi ti wọn n f'ọrọ wa a lẹnu wo lọwọlọwọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI