#ENDSARS: IFẸHONU HAN GBỌNA ARA YỌ, WỌN TUN DANA SUN ILEEṢẸ TINUBU L'EKOO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, October 21, 2020

#ENDSARS: IFẸHONU HAN GBỌNA ARA YỌ, WỌN TUN DANA SUN ILEEṢẸ TINUBU L'EKOO


Bi ẹ ṣe n ka iroyin yii, ileeṣẹ tẹlifiṣan Aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu APC, Ahmed Tinubu, iyẹn Television Continental to wa lagbegbe Ketu nilu Eko l'awọn ọd\to n fẹhonu han ti n dana sun bayii, ti a si gbọ pe wọn ti kuro lori afẹfẹ lasiko ta a kọ iroyin yii tan.


Gbajumọ eto kan ti wọn pe ni Ero Re', iyẹn Your View la gbọ pe o n lọ lọwọ ko t o di pe tọọgi yawọ ileeṣẹ tẹlifiṣan naa, ti wọn si bẹrẹ si i f'ibinu ṣe awọn oṣiṣẹ to wa nibẹ leṣe.

Ẹni to n ṣe eto naa lọwọ, Morayọ Afọlabi-Brown lo kọkọ kede sita wi pe awọn tọọgi ti yawọ inu ọgba naa pẹlu bọọsi loriṣiriṣi, to si kede wi pe awọn yoo kuro lori afẹfẹ fungba diẹ.

A gbọ pe pẹlu ibinu ni wọn dana sun ileeṣẹ tẹlifiṣan naa, nitori igbagbọ wi pe Aṣiwaju Tinubu lo ra awọn ṣọja lati ọọ koju awọn eeyan ni too geeti Lekki lalẹ ana.

Oriṣiriṣi fidio bi wọ ṣe danu sun tẹlifiṣan naa lo ti wa lori ikanni ayelujara bayii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI