Bí ẹ ṣe ń ka ìròyìn yìí, inú ìpàdé ikọkọ ni Ààrẹ Buhari wá pẹ̀lú àwọn aṣofin kan n'ilu Abuja.
Ohun ti a gbọ ìpàdé náà dá lórí ọ̀nà láti fi òpin sí iwọde àwọn ọdọ káàkiri orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, èyí tí wọn fi ń fẹhonu hàn lórí àwọn ọlọpaa SARS àti SWAT.
Lati bí ọjọ́ mélòó kan sẹ́yìn làwọn ọdọ káàkiri orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí làwọn kò nífẹ̀ẹ́ sì báwọn ọlọpaa àtàwọn ọlọpaa kogberegbe, ìyẹn SARS ṣe ń fìyà jẹ àwọn ọdọ lọ́nà tí kò bá òfin mú.
Lára àwọn tó wà níbi ìpàdé pẹ̀lú Ààrẹ Buhari ni Ààrẹ ilé igbimọ aṣofin, Ahmed Lawan àti Ọnọrebu Fẹmi Gbajabiamila.
No comments:
Post a Comment