Gbogbo awọn to ji awọn ẹru ijọba ati t'awọn ileeṣẹ aladani to fi mọ awọn ounjẹ konilegbele kaakiri orilẹ-ede yii ni wọn ti wa ninu wahala nla bi ẹ ṣe n ka iroyin yii, ti igbagbọ si wa pe o ṣee ṣe ki gbogbo wọn fi ẹnu fẹra bi abẹbẹ.
Latigba ti iwọde ifẹhonu han ti ENDSARS ti gba ọna mi in yọ láwọn eeyan ti n ko awọn ẹru iranwọ fun isede konilegbele l'awọn ibi ti ijọba ko wọn pamọ si.
Bo tilẹ jẹ pe l'awọn ipinlẹ kọọkan lorilẹ-ede yii l'awọn to n ji dukia gbe ti bẹrẹ si i daa pada diẹ-diẹ, ṣugbọn sibẹ ọwọ palaba awọn kan ti n segi, ti wọn si ti wa lahamọ awọn agbofinro kaakiri Naijiria.
Eyi ni diẹ lara awọn tọwọ palaba wọn ti segi
No comments:
Post a Comment