EEYAN MEJI SỌDA SỌRUN NIBI IKỌLU AWỌN ỌMỌ ẸGBẸ OKUNKUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, October 8, 2020

EEYAN MEJI SỌDA SỌRUN NIBI IKỌLU AWỌN ỌMỌ ẸGBẸ OKUNKUN


Ko din ni eeyan meji ti wọn padanu ẹmi wọn nibi t'awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti kọju ija s'ira wọn nilu Abraka, ipinlẹ Delta.

Awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun Eiye ati Aiye ni wọn fi agba han ara wọn, t'awọn meji si gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra.

Wọn lo o ti pẹ t'awọn eeyan naa ti n leri iku sira wọn, ko to o di pe wọn pada fojukoju lọjọ t'iṣẹlẹ buruku yii waye.

 

Iro awọn ọlọpaa t'awọn eeyan naa gbọ lo mu ki wọn ba ẹsẹ wọn sọrọ, ta a si gbọ pe awọn ọlọpaa ṣi n wa awọn to na papa bora titi ta a fi pari iroyin yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI