Ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara lábẹ́ ìṣàkóso Gómìnà AbdulRahman AbdulRazaq tí kéde wí pé ọjọ́ Abamẹta-Satide tó ń bọ̀ yìí ni ìdánwò àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọn fẹẹ wọ girama, ìyẹn Common Entrance yóò wáyé káàkiri ipinlẹ náà.
Kọmiṣanna fún ọ̀rọ̀ ètò ẹ̀kọ́ ni ipinlẹ náà, Hajia Fatimah Bisọla lo fi ìròyìn náà síta wí pé ọjọ́ kọlanlelọgbọn oṣù yìí ni idanwo náà yóò wáyé.
Ó ní ọjọ́ Satide-Abamẹta tó kọjá, ìyẹn ọjọ́ kẹrinlelogun lo yẹ kí ìdánwò náà wáyé, ṣùgbọ́n tí wọn so rọ̀ nítorí rògbòdìyàn tí #ENDSARS tó wáyé kọjá.
No comments:
Post a Comment