Ààrẹ ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ni lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Ọ̀mọ̀wé Olusọji Aderẹmi Fajẹnyọ tí gba àwọn àkànṣe àdúrà fáwọn ọmọ àti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà káàkiri àgbáyé.
Ọ̀mọ̀wé Fajẹnyọ to tún jẹ́ Alakoso ẹ̀ka imọ èdè Yorùbá nílé ẹ̀kọ́ àwọn olùkọ́ni tí kọlẹẹji tilu Abẹ́òkúta, ìyẹn Federal College of Education, Abẹ́òkúta, ìpínlẹ̀ Ogun lo ṣe àdúrà náà laaarọ òní, ọjọ́ kinni oṣù kẹwàá ọdún 2020.
Èyí ni ẹ̀bẹ̀ àdúrà rẹ sì Elédùmarè
Oṣù kẹwàá la wọ̀
K'Elédùwà fi ohun gbogbo kẹ́ wa
K'íre wá wa wá
K'ọ́mọ wá wa wá
K'ájé wá wa wá
K'àlàáfíà wá wa wá
Kí àìkú baálẹ̀ ọrọ̀ wá wa wá
Èyí a wá wi k'árọ̀ o rọ̀ mọ
Àṣẹ wàá ni t'ìrèké.
Síwájú sí í lo tún gbàdúrà pe
Òní l'àyájọ́ òmìnira
Kí òmìnira má ṣe di omi ìnira fún wa
K'ára má ṣe ni wá
Ká a má ṣe rí ìnira
Ká a má ṣe rí ìnira nílé
Ká a má ṣe rí ìnira lọ́nà
Kí ìgbà ó dẹ̀ wá
Bí igbà ṣe n dẹ kòkó l'ágbàlá
No comments:
Post a Comment