AGBARIJỌ ILEEṢẸ ELETO ỌRỌ-AJE TUN YẸYẸ BUHARI NITA GBANGBA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, October 7, 2020

AGBARIJỌ ILEEṢẸ ELETO ỌRỌ-AJE TUN YẸYẸ BUHARI NITA GBANGBA


Agbarijọ awọn ileeṣẹ to n ṣakoso eto ọrọ aje lorilẹ-ede Naijiria, Nigerian Economic Society lọjọ Iṣẹgun-Tuside ana ti sọ nita gbangba wi pe eto iṣuna at9i ọrọ aje orilẹ-ede Naijiria labẹ iṣakoso Aarẹ Muhammadu Buhari ti dorikodo patapata.

Ọrọ yii waye lati ẹnu Aarẹ ẹgbẹ naa, Ọjọgbọn Sarah Anyanwu nibi irin ajo to lewaju awọn ikọ rẹ lọ s'ọdọ awọn aṣofin to kerejulọ, iyẹn Senate Minority Caucus, nibẹ lo ti sọ pe eto iṣuna labẹ iṣakoso Aarẹ Buhari ku diẹ kaato.

 
Ọjọgbọn Sarah sọ pe ọwọ ti Aarẹ Buhari fi n mu eto ọrọ aje Naijiria ti fi han daju pe ko mọ nnkan to n lọ, nitori pe iwa ailafojusun ni Aarẹ n hu si i, ati pe ibi ti wọn n dari eto ọrọ aje naa lọ ni ko ye wọn, ti ko si tun ye awọn ọmọ ilu.

O ni nnkan to ṣeni laaanu ni pe Aarẹ Buhari ko pe awọn ọjọgbọn l'ẹka eto ọrọ ajẹ ati eto iṣuna si iṣakoso eto ọrọ aje orilẹ-ede, eyi ni o ku diẹ kaato, ati pe ko bojumu to.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI