Kii saba wọpọ ki eeyan ri obinrin Musulumi nita lati maa ṣiṣẹ wolii, gẹgẹ b'awọn obinrin ẹlẹsin Kristẹni ti n ṣe e.
Amọ ti Wolii obinrin Mistura Oseni Akintunde, ẹni to n ṣiṣẹ wolii nilana ẹsin Islam yatọ.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori iwa ifipabanilopọ, Wolii Akintunde ni kii ṣe bi obinrin ba ṣe mura lo n fa iwa ifipabanilopọ, gẹgẹ bi awọn eeyan kan ṣe lero.
Amọ o ṣalaye pe bi a ba ṣe wo ara wa loju si, boya ọkunrin ni abi obinrin lo n fa iwa ifipabanilopọ.
Akintunde fikun pe, kii ṣe awọn ọkunrin nikan lo n huwa ifipabanilopọ, gẹgẹ bi awujọ wa ṣe lero, amọ awọn obinrin gan n fipa bani lopọ, ko si yẹ ka maa pariwo awọn ọkunrin nikan.
O wa tako ẹwọn ọdun mejidinlogun ti wọn n fun awọn eeyan to n fipa bani lopọ, eyi to ni ko to fun ijiya ẹṣẹ wọn .
Bakan naa lo rọ awọn eeyan lati ye ko awọn ti wọn ba fi tipa ba lopọ laya jẹ lori ayelujara, amọ n ṣe lo yẹ ki wọn ṣewuri fun wọn lati jade sita sọ tẹnu wọn.
Lati: BBC
No comments:
Post a Comment