ORIIRE NLA! IJỌBA KWARA FẸẸ DA RAṢIDI YẸKINI L'ỌLA LẸYIN ỌPỌLỌPỌ ỌDUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, September 11, 2020

ORIIRE NLA! IJỌBA KWARA FẸẸ DA RAṢIDI YẸKINI L'ỌLA LẸYIN ỌPỌLỌPỌ ỌDUN


Gbogbo eto lo ti fẹẹ pari bayii fun ijọba ipinlẹ Kwara labẹ Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lati yi orukọ papaa iṣere t'ilu Ilọrin si orukọ gbajugbaja agbabọọlu agbaye nni, Raṣhidi Yẹkini to ti doloogbe.

Gomina Abdurazaq fi eyi lede lasiko ti o lọ ṣe abẹwo ikini si minisita fun ere idaraya ati idagbasoke awọn ọdọ, Sunday Dare ni ọfiisi rẹ to wa n'ilu Abuja.

Abdulrazaq ni ijiroro awọn da lori ọna lati mu idagbasoke ba awọn ọdọ lawujọ.

O ni ijọba oun yoo fi abadofin ti yoo yi orukọ papa iṣere naa pada si orukọ Yẹkini ranṣẹ si Ile Igbimọ Asọfin ipinlẹ naa.

Ninu ọrọ idupẹ rẹ, Minisita naa ni ọpọ igba ni awọn ti kọ lẹta si ipinlẹ Kwara, lati gbe igbesẹ ti ko ni jẹ ki orukọ gbajugbaja elerebọọlu naa parẹ lailai.

Dare rọ ijọba ipinlẹ Kwara lati tẹsiwaju ninu igbiyanju wọn, lati mu idagbasoke ba awọn ọdọ ni agbegbe wọn.

O ni igbelarugẹ ati ipese iṣẹ fun awọn ọdọ lawujọ ni yoo mu ki iwa ibajẹ dinku lorilẹ-ede Niajiria.

Ọjọ Kẹrin, Oṣu Karun un, ọdun 2012 ni agbabọọlu Naijiria naa papoda ni ilu Ibadan ni ẹni ọdun mejidinlaadọta (48years).

O bẹrẹ ere bọọlu pẹlu UNTL Kaduna ni ọdun 1981, to si tẹsiwaju lọ darapọ mọ ikọ agbabọọlu Naijiria ati Yuroopu.

Nibẹ lo ti gba bọọlu fun ọdun mẹrin pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Vitoria Setubal ni Portugal, to si tun gba ami ẹyẹ ẹni to gba bọọlu wọ inu awọn julọ ninu idije Primeira Liga ni saa ọdun 1993 si 1994.

Yekini 

Gẹgẹ bi agbabọọlu fun ikọ Naijiria, Yẹkini gba bọọlu wọ inu awọn ni igba mẹtadinlogoji, ti o si ṣoju Niajiria ninu idije gboogi marun pẹlu Idije agbaye meji.

Ni ibẹ ni o ti kọkọ jẹ ẹni akọkọ ti yoo gba bọọlu wọ inu awọn fun Naijiria ninu Idije Agbaye.

Ọdun 1993 ni o gba ami ẹyẹ Agbabọọlu Ilẹ Afrika to lamilaaka julọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI