ORÍ-IRE NLA: ÀWỌN Ọ̀DỌ́ ẸGBẸ̀RÚN MẸ́WÀÁ FẸẸ JẸ ÌGBÁDÙN MÙDÙNMÚDÙN ETO ÒṢÈLÚ ALÁGBÁDÁ NÍ KWARA PẸ̀LÚ ÌMỌ̀ AYÉLUJÁRA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, September 1, 2020

ORÍ-IRE NLA: ÀWỌN Ọ̀DỌ́ ẸGBẸ̀RÚN MẸ́WÀÁ FẸẸ JẸ ÌGBÁDÙN MÙDÙNMÚDÙN ETO ÒṢÈLÚ ALÁGBÁDÁ NÍ KWARA PẸ̀LÚ ÌMỌ̀ AYÉLUJÁRA


Bí ẹ ṣe ń ka ìròyìn yìí, kò sì orin méjì táwọn ara ìpínlẹ̀ Kwara lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà ńkọ báyìí to yàtọ̀ sí orin ọpẹ lórí bí ìjọba ìpínlẹ̀ náà lábẹ́ Gómìnà AbdulRahman AbdulRazaq ṣe lòun ṣetán láti ro àwọn ọdọ tí kò din ni ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá lágbára.

Ọ̀sẹ̀ mẹ́ta gbáko là gbọ pé àwọn ọdọ yóò fi  jẹ àǹfààní ìdánilẹkọọ ọ̀fẹ́ yìí, tí iforukosilẹ yóò sì bẹ̀rẹ̀ láàárín òní, ọjọ́ kínní sí ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kẹsàn-án ọdún 2020 tí a wà yìí. 

Orí ayélujára là gbọ pé àwọn ọdọ náà yóò ti gba ìdánilẹkọọ yìí tí wọn pé ní Virtual Digital Training. 

AWIKONKO gbọ pé ẹlẹẹkeji rèé tí irú àǹfààní báyìí yóò máa wáyé pẹ̀lú bí ìjọba ṣe ń fi ojú sọna láti d'awọn ọdọ tí kò dín ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ́n lọ́lá láàárín ọdún mẹta. 

Ninu oṣù kẹrin ọdún yìí ni àwọn ọdọ ẹgbẹ̀rún mẹta tí kọ́kọ́ jẹ́ àǹfààní tí kò wọ́pọ̀ yìí, tí wọn sì ti dá dúró láàyè ara wọn látìgbà náà. 

Gẹ́gẹ́ bí a tún ṣe gbọ́, ọ̀nà láti dín àìríṣẹ ṣe àwọn ọdọ dínkù láwùjọ lo mú kí ìjọba gbé igbese eto ti wọn pé ní Kwara State Social Investment Programmes (KWASSIP) silẹ táwọn èèyàn sì ń jẹ àǹfààní loriṣiriṣi lábẹ́ rẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI